John 12:1-8

A fi ààmì òróró yàn Jesu ni Betani

1 aNítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 2Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.

4 bNígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, 5“Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” 6 cṢùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.

7 dNígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. 8Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”

Copyright information for YorBMYO